Search our sites

Search past winners/finalists


  • MESA logo
  • SATE logo

Yorùbá

IBA Montage

A fìwépe ilé-iṣẹ́ rẹ láti fa àwọn tí a yàn kalẹ̀ sí Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie® Fún Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣòwò (Ọlọ́dún 22) ti 2025. Ètò àwọn ẹ̀yẹ ìṣòwò àkọ́ṣe ní àgbáyé pàápàá jùlọ fún àwọn obìnrin ni a ṣe nípasẹ̀ àwọn olùṣẹ̀dá  International Business Awards® àti American Business Awards® tó gbajùmọ́.

Tí o bá fẹ́ gba ìwé ìkópa, tí ń sọ nípa àwọn ìtọ́ni tó péye nípa bí o ti le gbáradì kí o sì fa àwọn tí o yàn kalẹ̀, fa àdírẹ́ẹ̀sì í-meèlì rẹ kalẹ̀ níbí a ó sì firánṣẹ́ nípasẹ̀ í-meèlì sí ọ. A ní òfin ìpamọ́ tí kò gba gbẹ̀rẹ́ a kò sì ní ṣàpínlò àdírẹ́ẹ̀sì í-meèli rẹ pẹ̀lú ẹlòmíràn, fún èyíkéyìí èrèdí.

 

Èyí ni ojú-ewé kan ṣoṣo lórí ojúlé-wẹ́ẹ̀bù yìí tí wàá rí ní èdè yìí. Gbogbo ojú-ewé míràn wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, bí ó ti jẹ́ ìwé ìkópa. Èyí jẹ́ nítorí a bèrè wípé kí a fa yíyani sílẹ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sí, kí àwọn gbajúgbajà ìṣòwò káàkiri àgbáyé le kópa nínu ìgbésẹ̀ dídájọ́.

Nípa Stevie Awards for Women in Business “Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie fún Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣòwò”

Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie fún Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣòwò ń bu ọlá fún àwọn àṣeyọrí obìnrin tí ń ṣòwo, ọ̀gá ilé-iṣẹ́, òṣìṣẹ́ àti àwọn ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ń drí, káàkiri àgbàyé. Ilé-iṣẹ́ Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie, èyítí ń fúnni ní àmì ẹ̀yẹ náà, wà ní orílẹ̀-èdè United States.   Wọ́n jẹ́ agbátẹrù ti oríṣìí ìdíje Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie mẹ́jọ, èyítí o le kọ́ nípa rẹ̀ ní www.StevieAwards.com.  Ẹ̀bùn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie ti di ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn àgbáyé tí ènìyàn le gbà.

Ní 2024, Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie fún Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣòwò ni a fún àwọn ilé-iṣẹ́ àti ẹnikọ̀ọ̀kan láti ju orílẹ̀-èdè 30. Ṣíra tẹ ibí láti wo àkójọ kan ti àwọn tó borí nínú ìdíje ti 2024.

Àwọn ìsọ̀rí

Oríṣìí ìsọ̀rí àmìn ẹ̀yẹ ló wà láti yàn nínú Stevie Awards for Women in Business “Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie fún Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣòwò”. Tí o bá yàn láti kópa, wàá yan àwọn ìsọ̀rí tó dọ́gba pẹ̀lú àwọn àṣeyọrí tí o fẹ́ ká fi dá ilé-iṣẹ́ rẹ mọ̀, wàá sì gbáradì fún yíyàn rẹ gẹ́gẹ́ bíi àwọn ìtọ́ni fún àwọn ìsọ̀rí náà. Láàrín àwọn ìsọ̀rí tó wà nílẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí:

  •  Àwọn Ìsọ̀rí Àmìn Ẹ̀yẹ Obìnrin Kọ̀ọ̀kan, èyí pẹ̀lú  
    • Obìnrin Oníṣòwò ti Ọdún Náà
    • Obìnrin Ọlọ́gbọ́n-inú ti Ọdún Náà
    • Obìnrin Ọ̀gá Ilé-iṣẹ́ ti Ọdún Náà
    • Obìnrin Òṣìṣẹ́ ti Ọdún Náà
  • Àwọn Ìsọ̀rí Àmìn Ẹ̀yẹ Ibi-iṣẹ́/Ilé-iṣẹ́ (Èyítí-Obìnrin Ni tàbí Darí)
  • Àwọn Ìsọ̀rí Àmìn Ẹ̀yẹ Àgbéjáde Titun àti Iṣẹ́ (Èyítí-A Ṣe Fún/Nípasẹ̀ Obìnrin)
  • Àwọn Ìsọ̀rí Àmìn Ẹ̀yẹ Ìbánisọ̀rọ̀ àti Ìpolówó Ọjà (Èyítí-A Ṣe Fún/Nípasẹ̀ Obìnrin)
  • Àwọn Ìsọ̀rí Àmìn Ẹ̀yẹ Midia (Èyítí-A Ṣe Fún/Nípasẹ̀ Obìnrin)
  • Àwọn Ìsọ̀rí Ohun Àṣeyọrí

Àkójọ àti àpèjúwe ti àwọn ìsọ̀rí, àwọn àmúyẹ ìfàkalẹ̀ fún ìkọ̀kan, ọjọ́ ìdópin ìwọlé, àti ìsanwó tó nílò ni a tọ́kasí nínú ìwé ìwọlé náà.

Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ

Awọn olubori ti Stevie Awards fun Awọn Obirin ni Iṣowo ni yoo kede ni Oṣu Kẹsan Ọjọ 19. Lẹhinna, Awọn olubori Award Gold, Silver ati Bronze Stevie ni yoo gbekalẹ ni ounjẹ alẹ gala ni Ilu New York. Lakoko ayeye Gold, Silver ati Bronze Stevie Awards yoo ṣe afihan si awọn olubori.

Àwọn olùbásọ̀rọ̀

Jọ̀wọ́ kàn sí wa pẹ̀lú èyíkéyìí ìbéèrè tí o le ní nípa   Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie náà fún Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣòwò tàbí ọ̀kan nínú àwọn ètò ti Àwọn Àmìn Ẹ̀yẹ Stevie míràn.

The Stevie Awards
10560 Main Street, Suite 519
Fairfax, Virginia 22030, USA
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀: : +1 703-547-8389
Fakisi: +1 703-991-2397
Í-meèlì: help@stevieawards.com